Ilé tí ó dojúkọ ìta gbangba ìṣèré ilé Ọlọ́run náà ní ìhà ìwọ̀ òòrùn jẹ́ àádọ́rin ìgbọ̀nwọ́ ni fífẹ̀. Ògiri ilé náà nípọn tó ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún yípo, gígùn rẹ̀ sì jẹ́ àádọ́rùn-ún ìgbọ̀nwọ́.