Ísíkẹ́lì 39:1-3 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. “Ọmọ ènìyàn, ṣọtẹ́lẹ̀ sí Gógù, kí ó sì wí pé: ‘Èyí yìí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: Èmi lòdì sí ọ, Ìwọ Gógì, olórí ọmọ-aládé ti Mésékì àti Túbálì.

2. Èmi yóò dá ọ padà, èmi yóò sì darí rẹ. Èmi yóò mú ọ wá láti jìnnàjìnnà ìhà àríwá, Èmi yóò rán ọ lòdì sí orí àwọn òkè gíga Ísírẹ́lì.

3. Nígbà náà èmi yóò lu ọrùn awọ rẹ ní ọwọ́ òsì rẹ, èmi yóò sì mú kí àwọn ọfà rẹ jábọ́ ni ọwọ́ ọ̀tún rẹ.

Ísíkẹ́lì 39