33. “ ‘Èyí yìí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: Ní ọjọ́ tí mo wẹ̀ yín kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ yín gbogbo, èmi yóò ṣe àtúnṣe àwọn ìlú yín, wọn yóò sì ṣe àtúnkọ́ iwólulẹ̀
34. ilẹ̀ ahoro náà ní àwa yóò tún kọ́ ti kì yóò wà ní ahoro lójú àwọn tí ó ń gba ibẹ̀ kọjá mọ́.
35. Wọn yóò sọ wí pé, “Ilẹ̀ yìí tí ó ti wà ní ṣíṣòfo tẹ́lẹ̀ ti dà bí ọgbà Édẹ́nì; àwọn ìlú tí ó wà ní wíwó lulẹ̀, ahoro tí a ti parun, ni àwa yóò mọdi sí tí yóò sì wà fún gbígbé ni ìsìnyí.”