20. Gbogbo ibi tí wọ́n lọ ní àárin àwọn orílẹ̀ èdè ni wọn ti sọ orúkọ mímọ́ mi di aláìmọ́, nítorí tí a sọ nípa wọn pé, ‘Ìwọ̀nyí ni àwọn ènìyàn Olúwa, síbẹ̀ wọn ní láti fí ilẹ̀ náà sílẹ̀.’
21. Orúkọ mímọ́ mi jẹ́ mi lógún, èyí tí ilé Ísírẹ́lì sọ di aláìmọ́ ni àárin àwọn orílẹ̀ èdè tí wọ́n ti lọ.
22. “Nítorí náà, sọ fún ilé Ísírẹ́lì, ‘Èyí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: Kì í ṣe nítorí rẹ, ìwọ ilé Ísírẹ́lì, ni èmi yóò ṣe ṣe àwọn nǹkan wọ̀nyí, ṣùgbọ́n nítorí orúkọ mímọ́ mi, èyí ti ìwọ ti sọ di aláìmọ́ ní àárin àwọn orílẹ̀ èdè tí ìwọ ti lọ.