6. “Nítorí náà, mí ìmí ẹ̀dùn ìwọ ọmọ ènìyàn! Mi ìmí ẹ̀dùn pẹ̀lú ọkàn ìbànújẹ́ àti ẹ̀dùn ọkàn kíkorò ní iwájú wọn.
7. Bí wọ́n bá sì bi ọ́, wí pé, ‘Kí ni ó dé tí ìwọ fi ń mi ìmí ẹ̀dùn?’ Ìwọ yóò wí pé, ‘Nítorí ìròyìn tí ó ń bẹ. Gbogbo ọkàn ni yóò yọ́, gbogbo ọwọ́ ni yóò sì di aláìlera; gbogbo ọkàn ní yóò dákú, gbogbo eékún ni yóò sì di aláìlera bí omi?’ Ó ń bọ̀! Yóò sì wa sí ìmúṣẹ dandan, ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.”
8. Ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá:
9. “Ọmọ ènìyàn, sọ tẹ́lẹ̀ wí pé, Èyí yìí ní Olúwa wí:“ ‘Ìdá kan, Ìdá kan,tí a pọ́n tí a sì kùn
10. a ti pọ́n fún pípa,a sì dan an kí ó lè máa kọ bí mọ̀nàmọ́ná!“ ‘Àwa yóò ha si ọ̀pá aládé ọmọ mi Júdà? Idà kẹ́gàn gbogbo ọ̀pá.
11. “ ‘Idà ní a yàn láti pọ́n,kí ó lè ṣe é gbá mú;a pọ́n ọn a sì dan án,ó ṣetán fún ọwọ́ àwọn apani.