47. Sọ fún igbo ìhà gúsù: ‘Gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa. Èyí ní ohun tí Olúwa Ọlọ́run wí: Kíyèsí í, èmi yóò dá iná kan nínú rẹ̀ yóò sì jó olúkúlùkù igi tutu nínú rẹ̀, àti olúkúlùkù igi gbígbẹ. Jíjí ọwọ́ iná náà kò ní i ṣe e pa, àti gbogbo ojú láti gúsù dé aríwá ni a ó sun nínú rẹ̀.
48. Gbogbo ènìyàn yóò sì mọ̀ pé Èmi Olúwa ni ó dá a, a kì yóò sì le è pa á.’ ”
49. Nígbà náà ni mo wí pé, “Áà! Olúwa Ọlọ́run! Wọn ń sọ fún mi pé, ‘Kì í wa ṣe pé òwe lo ń pa bí?’ ”