40. Wọn yóò pe àjọ ènìyàn jọ lé ọ lórí, àwọn tí yóò sọ ọ́ ní òkúta, ti wọn yóò sì fi idà wọn gé ọ sí wẹ́wẹ́.
41. Wọn yóò jo gbogbo ilé rẹ palẹ̀ wọn yóò sì fi ìyà jẹ ọ́ ní ojú àwọn obìnrin. Èmi yóò fi òpin sí àgbèrè ṣíṣe rẹ. Ìwọ kò sì ní san owó fún àwọn olólùfẹ́ rẹ mọ́.
42. Nígbà náà ni ìbínú mi sí Ọ yóò rọ̀, owú ìbínú mi yóò sì kúrò lọ́dọ̀ rẹ; inú mi yóò rọ, èmi kò sì ní bínú mọ́.
43. “ ‘Nítorí pé o kò rántí ọjọ́ èwe rẹ ṣùgbọ́n ìwọ ń rí mi fín pẹ̀lú gbogbo nǹkan wọ̀nyí, ó dájú pé Èmi yóò mú gbogbo ohun tí ìwọ ti ṣe wa sórí rẹ, ni Olúwa Ọlọ́run wí, Ìwọ kì yóò sì ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ yìí ni orí gbogbo ohun ìríra rẹ?