Ìfihàn 9:9-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

9. Wọn sì ní ìgbàyà tí ó dàbí ìgbàyà irin; ìró ìyẹ́ wọn sì dàbí ìró kẹ̀kẹ́ ẹsin púpọ̀ tí ń súré lọ sí ogun.

10. Wọ́n sì ni ìrù àti oró bí tí àkéekèe, àti ní ìrù wọn ni agbára wọn wà láti pa ènìyàn lára fún oṣù márùn-ún.

11. Wọ́n ní ańgẹ́lì ọ̀gbun náà bí ọba lórí wọn, orúkọ rẹ̀ ní èdè Hébérù ní Ábádónì, àti ni èdè Gíríkì orúkọ rẹ̀ a máa jẹ́ Àpólíónì.

12. Ègbé kan tí kọjá, kíyèsi i, ègbé méjì ń bọ̀ síbẹ̀ lẹ́yìn èyí.

Ìfihàn 9