Ìfihàn 9:19-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

19. Nítorí pé agbára àwọn ẹṣin náà ń bẹ ní ẹnu wọn àti ní ìrù wọn: Nítorí pé ìrù wọn dàbí ejò, wọn sì ní orí, àwọn wọ̀nyí ni wọn sì fi ń pani lára.

20. Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn ìyókù tí a kò sì ti ipa ìyọnu wọ̀nyí pa, kò sì ronúpìwàdà iṣẹ́ ọwọ́ wọn, kí wọn má ṣe fàdákà, àti ti idẹ, àti òkúta, àti ti igi mọ́: àwọn tí kò lè ríran, tàbí kí wọn gbọ́ràn, tàbí kí wọn rìn:

21. Bẹ́ẹ̀ ni wọn kò ronúpìwàdà ìwà ìpànìyàn wọn, tàbí oṣó wọn tàbí àgbérè wọn, tàbí olè wọn.

Ìfihàn 9