Ìfihàn 3:1-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. “Àti sí Ańgẹ́lì ìjọ ni Sádísì kọ̀wé:Ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ni ẹni tí ó ni Ẹ̀mí méje Ọlọ́run, àti ìràwọ̀ méje wí pé: Èmi mọ̀ iṣẹ́ rẹ̀, àti pé ìwọ ni orúkọ pé ìwọ ń bẹ láàyè, ṣùgbọ́n ìwọ ti kú.

2. Jí, kí o sì fi ẹsẹ̀ ohun tí ó kù múlẹ̀, tí ó ṣetán láti kú: Nítorí èmi kò rí iṣẹ́ rẹ ni pípé níwájú Ọlọ́run.

3. Nítorí náà rántí bí ìwọ ti gbà, àti bí ìwọ ti gbọ́, kí o sì pa á mọ́, kí o sì ronúpìwàdà. Ǹjẹ́, bí ìwọ kò ba ṣọ́ra, èmi yóò dé sí ọ bí olè, ìwọ kì yóò sì mọ́ wákàtí tí èmi yóò dé sí ọ.

4. Ìwọ ní orúkọ díẹ̀ ní Sádísì, tí kò fi aṣọ wọn yí èérí; wọn yóò sì máa ba mi rìn ní aṣọ funfun: nítorí wọ́n yẹ.

5. Ẹni tí ó bá ṣẹ́gun, òun náà ni a ó fi aṣọ funfun wọ̀; èmi kì yóò pa orúkọ rẹ̀ kúrò nínú ìwé ìyè, ṣùgbọ́n èmi yóò jẹ́wọ́ orúkọ rẹ̀ níwájú Baba mi, àti níwájú àwọn áńgẹ́lì rẹ̀.

6. Ẹni tí ó ba létí, kí ó gbọ́ ohun tí Ẹ̀mí ń ṣọ fún àwọn ìjọ.

7. “Àti sí Ańgẹ́lì Ìjọ ni Filadéfíà Kọ̀wé:Ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ni ẹni tí ó jẹ́ mímọ́ náà wí, ẹni tí ó ṣe olóòótọ́, ẹni tí ó ní kọ́kọ́rọ́ Dáfídì, ẹni tí ó sí, tí kò sí ẹni tí yóò tì; ẹni tí o sì tì, tí kò sì ẹni tí yóò ṣí i:

8. Èmi mọ iṣẹ́ rẹ̀: kíyèsí i, mo gbe ilẹ̀kùn tí ó ṣí kálẹ̀ níwájú rẹ̀, tí kò sí ẹni tí o lè tì í; pé ìwọ ni agbára díẹ̀, ìwọ sì pa ọ̀rọ̀ mi mọ́, ìwọ kò sì sẹ́ orúkọ mi.

9. Kíyèsí i, èmi ó mú àwọn ti sínágógù Sàtánì, àwọn tí wọ́n ń wí pé Júù ni àwọn, tí wọn kì í sì ṣe bẹ́ẹ̀, ṣùgbọ́n tí wọn ń ṣèké; kíyèsí i, èmi ó mú kí wọn wá wólẹ̀ níwájú ẹṣẹ̀ rẹ̀, kí wọn sì mọ̀ pé èmi tí fẹ́ ọ.

Ìfihàn 3