Ìṣe Àwọn Àpósítélì 25:1-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Lẹ́yìn ọjọ́ méta tí ó dé sí ilẹ̀ náà, Fésítúsì gòkè láti Kesaríà lọ sì Jerúsálémù,

2. ní ibi tí àwọn olórí àlùfáà àti àwọn ènìyàn pàtàkì nínú àwọn Júù ti gbé ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan Pọ́ọ̀lù wá síwájú rẹ̀.

3. Wọ́n tọrọ lọ́wọ́ Fẹ́sítúsì, kí ó bá le se ojúrere fuń wọn, kí ó bá à lè jẹ́ kí wọn mú Pọ́ọ̀lù wá sí Jerúsálémù, wọn ń gbìmọ̀ láti dènà dè é, kí wọn sì pa á ní ọ̀nà.

4. Ṣùgbọ́n Fẹ́sítúsì dáhùn pé, “A pa Pọ́ọ̀lù mọ́ ní Kesaríà, àti pé òun tíkara òun ń múra àti padà lọ ní lọ́ọ́lọ́ọ́ yìí.

5. Ẹ jẹ́ kí díẹ̀ nínú àwọn olórí yín bá mi sọ̀kalẹ̀ lọ láti fi ìdí ẹ̀sùn tí ẹ fi sun ọkùnrin náà múlẹ̀ níbẹ̀, bí ó bá ní ohun búburú kan tí ó wà lọ́wọ́ rẹ̀.”

Ìṣe Àwọn Àpósítélì 25