Ìṣe Àwọn Àpósítélì 22:22-24 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

22. Wọ́n sì fi etí sí ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù títí tí ó fi sọ ọ̀rọ̀ yìí. Nígbà yìí ni wọ́n gbé ohùn wọn sókè, wọ́n sì kígbe wí pé, “Ẹ mu ẹni yìí kúrò láyé! Kò yẹ kí ó wà láàyè!”

23. Bí wọ́n sì ti ń kígbe, tí wọ́n sì ń jú aṣọ wọn káàkiri, tí wọ́n ń ku eruku sí ojú ọ̀run,

24. olórí ogun pàṣẹ pé kí a mú Pọ́ọ̀lù wá sínú àgọ́ àwọn ológun. Ó sì pàṣẹ kí wọ́n ó lù ú, kí wọn fi ọ̀rọ̀ wa lẹ́nu wò, kí òun baà lè mọ ìdí tí wọ́n fi ń kígbe lé e lórí bẹ́ẹ̀.

Ìṣe Àwọn Àpósítélì 22