11. Éfúráímù jẹ́ ọmọ màlúù tí atí kọ́, to si fẹ́ràn láti máa pa ọkàlórí ọrun rẹ̀ tó lẹ́wà nièmi ó dí ẹru wúwo léÈmi yóò mú kí a gun Éfúráímù bí ẹṣinJúdà yóò tú ilẹ̀,Jákọ́bù yóò sì fọ́ ogúlùtu rẹ̀
12. Ẹ gbin òdòdó fún ara yínkí ẹ sì ká èso ìfẹ́ àìlópin,Ẹ tu ilẹ̀ yín tí a kòronítorí pé ó ti tó àsìkò láti wá Olúwa,títí tí yóò fi dé,tí yóò sì rọ òjò òdodo lé yín lórí.
13. Ṣùgbọ́n ẹ tí gbìn buburú ẹ si ka ibi,Ẹ ti jẹ èso èkénítorí ẹ tí gbẹ́kẹ̀ lé agbára yínàti àwọn ọ̀pọ̀ jagun jagun yín
14. ariwo ogun yóò bo àwọn ènìyàn yínkí gbogbo odi agbára yín ba le parun.Gẹ́gẹ́ bí Ṣalìmanì ṣe pa Bétí-Ábélì run lọ́jọ́ ogun,nígbà tí a gbé àwọn ìyá ṣánlẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn
15. Báyìí ni a o sì ṣe sí ọ, ìwọ Bétélì,nítorí pé ìwà buburú yín ti pọ̀jù.Ní àfẹ̀mọ́júmọ́ ọjọ́ náà,a o pa ọba Ísírẹ́lì run pátapáta.