9. ‘Ògo ìkẹyìn àwọn ọmọ-ogun ilé yìí yóò pọ̀ ju ti ìṣáájú lọ;’ ni Olúwa àwọn ọmọ ogun wí: ‘Àti ní ìhín yìí ni Èmi ó sì fi àlàáfíà fún ni’, ni Olúwa àwọn ọmọ ogun wí.”
10. Ní ọjọ́ kẹrìnlélógún oṣù kẹsàn-án ní ọdún kejì Dáríúsì, ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ wòlíì Hágáì wá pé:
11. “Báyìí ni Olúwa alágbára wí: ‘Béèrè lọ́wọ́ àwọn àlùfáà ohun tí òfin wí pé:
12. Bí ẹnìkan bá gbé ẹran mímọ́ ní ìṣẹ́tí aṣọ rẹ̀, tí ìṣẹ́tí aṣọ rẹ̀ kan Búrẹ́dì tàbí ọbẹ̀, wáìnì, òróró tàbí oúnjẹ mìíràn, ǹjẹ́ yóò ha jẹ́ mímọ́ bí?’ ”Àwọn àlùfáà sì dáhùn wí pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́.”
13. Nígbà náà ni Hágáì wí pé, “Bí ẹnìkan tí ó jẹ́ aláìmọ́ nipa fífi ara kan òkú bá fi ara kan ọkan lára nǹkan wọ̀nyí, ǹjẹ́ yóò ha jẹ́ aláìmọ́?”Àwọn àlùfáà sì dáhùn wí pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, yóò jẹ́ aláìmọ́.”