Hágáì 1:7-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

7. Báyìí ni Olúwa alágbára wí: “Ẹ kíyèsi ọ̀nà yín.

8. Ẹ gun orí àwọn òkè ńlá lọ, kí ẹ sì mú igi wá pẹ̀lú yín. Kí ẹ sì kọ́ ilé náà, kí inú mi bà leè dùn sí i, kí a sì yín mí lógo,” ni Olúwa wí.

9. “Ẹyin ti ń retí ọ̀pọ̀, ṣùgbọ́n kíyèsíi,, o yípadà sí díẹ̀. Ohun tí ẹ̀yin mú wa ilé, èmi sì fẹ́ ẹ dànù. Nítorí kí ni?” ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí. “Nítorí ilé mi tí ó dáhoro; tí olúkúlùkù yín sì ń sáré fún ilé ara rẹ̀.

10. Nítorí yín ni awọn ọ̀run ṣe dá ìrì dúró tí ilẹ̀ sì kọ̀ láti mu èso jáde.

Hágáì 1