Hábákúkù 2:2-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

2. Nígbà náà ni Olúwa dáhun pé:“Kọ ìṣípayá náa sílẹ̀kí o sí han ketekete lórí wàláàkí ẹni tí ń kà á, lè máa sáré.

3. Nítorí ìṣípayá náà jẹ́ tí ìgbà kan tí a múra sílẹ̀ dè;yóò máa yára sí ìgbẹ̀yinkí yóò sí sọ èkébí o tilẹ̀ lọ́ra, dúró dè é;nítorí, dájúdájú, yóò dé, kí yóò sí pẹ́”

4. “Kíyèsí, ọkàn rẹ tí ó gbéga;Ìfẹ́ rẹ̀ kò dúró ṣinṣin nínú rẹ̀,ṣùgbọ́n olododo yóò wa nípa ìgbàgbọ́ rẹ̀.

Hábákúkù 2