Gálátíà 1:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Pọ́ọ̀lù, Àpósítélì tí a rán kì í ṣe láti ọ̀dọ̀ ènìyàn wá, tàbí nípa ènìyàn, ṣùgbọ́n nípa Jésù Kírísítì àti Ọlọ́run Baba, ẹni tí ó jí i dìde kúrò nínú òkú.

2. Àti gbogbo àwọn arákùnrin tí ó wà pẹ̀lú mi,Sí àwọn ìjọ ní Gálátíà:

3. Oore-ọ̀fẹ́ sí yín àti àlàáfíà láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba wá àti Jésù Kírísítì Olúwa,

4. ẹni tí ó fí òun tìkararẹ̀ dípò ẹ̀ṣẹ̀ wa, kí ó lè gbà wá kúrò nínú ayé búburú ìsinsin yìí, gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ Ọlọ́run àti Baba wa,

Gálátíà 1