Ẹ́sítà 4:5-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

5. Nígbà náà ni Ẹ́sítà pe Hátakì, ọ̀kan nínú àwọn ìwẹ̀fà ọba tí a yàn láti máa jíṣẹ́ fún-un, ó pàṣẹ fún un pé kí ó béèrè ohun tí ó ń dààmú Módékáì àti ohun tí ó ṣe é.

6. Bẹ́ẹ̀ ni Hátakì jáde lọ bá Módékáì ní ìta gbangba ìlú niwájú ẹnu ọ̀nà ọba.

7. Módékáì sọ ohun gbogbo tí ó ṣẹlẹ̀ fún-un, papọ̀ pẹ̀lú iye owó tí Hámánì ti ṣe ipinnu láti san sínú àpò ìṣúra ọba fún ìparun àwọn Júù.

8. Ó sì tún fún un ní ọ̀kan lára ìwé tí ó gbé jáde fún ìparun àwọn, èyí tí a tẹ̀ jáde ní Ṣúṣà, láti fi han Ésítà kí ó sì ṣe àlàyé e rẹ̀ fún-un, ó sì sọ fún-un pé kí ó bẹ̀ ẹ́ kí ó lọ ṣíwájú ọba láti bẹ̀bẹ̀ fún àánú, kí ó bẹ̀bẹ̀ nítorí àwọn ènìyàn an rẹ̀.

9. Hátakì padà ó sì lọ ṣàlàyé fún Ẹ́sítà ohun tí Módékáì sọ.

10. Nígbà náà ni Ésítà pàṣẹ fún un pé kí ó sọ fún Módékáì,

11. “Gbogbo àwọn ìjòyè ọba àti àwọn ènìyàn agbègbè ìjọba rẹ̀ mọ̀ wí pé: fún ẹnikẹ́ni ọkùnrin tàbí obìnrin kan tàbí tí ó bá bá ọba sọ̀rọ̀ láì jẹ́ pé a ránsẹ́ pèé (ọba ti gbé òfin kan kalẹ̀ pé) kíkú ni yóò kú. Ohun kan tí ó le yẹ èyí ni pé, kí ọba na ọ̀pá a góòlùu rẹ̀ síi kí ó sì dá ẹ̀mí rẹ sí. Ṣùgbọ́n, ọgbọ̀n ọjọ́ ti kọjá tí a ti pè mí láti lọ sí ọ̀dọ̀ ọba.”

12. Nígbà tí a sọ ọ̀rọ̀ Ẹ́sítà fún Módékáì,

13. Ó sì rán ìdáhùn yí sí i pé; “Má ṣe rò pé nítorí pé ìwọ wà nílé ọba ìwọ nìkan lè yọ láàrin gbogbo àwọn Júù.

Ẹ́sítà 4