8. Nígbà tí a ti kéde òfin àti àṣẹ ọba, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọmọbìnrin ni a kó wá sí ilé ti ìṣọ́ Ṣúsà, sí abẹ́ ìtọ́jú Hégáì. A sì mú Ẹ́sítà náà wá sí ààfin ọba pẹ̀lú, a fà á lé Hégáì lọ́wọ́, ẹni tí ó jẹ́ alábojútó ilé àwọn obìnrin.
9. Ọmọbìnrin náà sì wù ú, ó sì rí ojú rere rẹ̀, lẹ́ṣẹ̀kẹ́ṣẹ̀ ó pèṣè àwọn ohun tí ó dára àti oúnjẹ pàtàkì fún-un. Ó sì yan àwọn ìránṣẹ́bìnrin wúndíá méje láti ààfin ọba òun àti àwọn ìránṣẹ́bìnrin náà lọ sí ibi tí ó dára jù nínú ilé àwọn obìnrin.
10. Ẹ́sítà kò tíì sọ nípa àwọn ènìyàn àti ìdílé e rẹ̀, nítorí Módékáì ti pàṣẹ fún-un pé kí ó má ṣe ṣọọ́.
11. Ní ojoojúmọ́ ni Módékáì máa ń rìn ní iwájú ilé àwọn obìnrin láti wo bí Ẹ́sítà ṣe wà àti ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí i.
12. Kí àkókò tó tó fún obìnrin kọ̀ọ̀kan láti lọ sí ọ̀dọ̀ ọba Ṣérísésì, ó ní láti lo ohun èlò tí ń mú ara lẹ́wà tí a yàn fún àwọn obìnrin fún oṣù méjìlá, yóò lo òróró òjía fún oṣù mẹ́fà, yóò sì lo ohun èlò olóòrùn dídùn tùràrí àti ìpara fún oṣù mẹ́fà pẹ̀lú.