Ẹ́sítà 2:3-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

3. Àti pé kí ọba kí ó yan àwọn aláṣẹ ní gbogbo agbégbé ilẹ̀ ọba láti kó gbogbo àwọn arẹwà ọmọbìnrin wọ̀nyí jọ sí ilé àwọn obìnrin ní ilé ìṣọ́ Ṣúṣà. Kí a kó wọn fún ìtọ́jú Hégáì, ìwẹ̀fà ọba, ẹni tí ó ṣe olùtọ́jú àwọn obìnrin; kí a ṣe ìtọ́jú u wọn dáradára.

4. Nígbà naà kí ọmọbìnrin tí ó bá tẹ́ ọba lọ́rùn kí ó jẹ́ ayaba dípò Fásítì.” Ìmọ̀ràn yìí tẹ́ ọba lọ́rùn, ó sì tẹ̀lé e.

5. Ó sì ṣe ní ìgbà náà ará a Júù kan wà ní ilé ìṣọ́ ti Ṣúsà, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Módékáì ọmọ Jáárì, ọmọ Símù, ọmọ Kúsì, ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì,

6. Ẹni tí Nebukadinésárì ọba Bábílónì ti gbé lọ sí ìgbèkùn láti Jérúsálẹ́mù, lára àwọn tí wọ́n kó ní ìgbèkùn pẹ̀lú ọba Jéóhákímù ọba Júdà.

7. Módékáì ní arákùnrin kan ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Hádásà, ẹni tí ó tọ́ dàgbà nítorí tí kò ní bàbá bẹ́ẹ̀ sì ni kò ní ìyá. Obìnrin yìí, ẹni tí a tún mọ̀ sí Ẹ́sítà, ó dára ó sì lẹ́wà, Módékáì mú u gẹ́gẹ́ bí ọmọ rẹ̀ nígbà tí bàbá àti ìyá rẹ̀ ti kú.

8. Nígbà tí a ti kéde òfin àti àṣẹ ọba, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọmọbìnrin ni a kó wá sí ilé ti ìṣọ́ Ṣúsà, sí abẹ́ ìtọ́jú Hégáì. A sì mú Ẹ́sítà náà wá sí ààfin ọba pẹ̀lú, a fà á lé Hégáì lọ́wọ́, ẹni tí ó jẹ́ alábojútó ilé àwọn obìnrin.

9. Ọmọbìnrin náà sì wù ú, ó sì rí ojú rere rẹ̀, lẹ́ṣẹ̀kẹ́ṣẹ̀ ó pèṣè àwọn ohun tí ó dára àti oúnjẹ pàtàkì fún-un. Ó sì yan àwọn ìránṣẹ́bìnrin wúndíá méje láti ààfin ọba òun àti àwọn ìránṣẹ́bìnrin náà lọ sí ibi tí ó dára jù nínú ilé àwọn obìnrin.

10. Ẹ́sítà kò tíì sọ nípa àwọn ènìyàn àti ìdílé e rẹ̀, nítorí Módékáì ti pàṣẹ fún-un pé kí ó má ṣe ṣọọ́.

11. Ní ojoojúmọ́ ni Módékáì máa ń rìn ní iwájú ilé àwọn obìnrin láti wo bí Ẹ́sítà ṣe wà àti ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí i.

12. Kí àkókò tó tó fún obìnrin kọ̀ọ̀kan láti lọ sí ọ̀dọ̀ ọba Ṣérísésì, ó ní láti lo ohun èlò tí ń mú ara lẹ́wà tí a yàn fún àwọn obìnrin fún oṣù méjìlá, yóò lo òróró òjía fún oṣù mẹ́fà, yóò sì lo ohun èlò olóòrùn dídùn tùràrí àti ìpara fún oṣù mẹ́fà pẹ̀lú.

Ẹ́sítà 2