Ẹ́sírà 8:34-36 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

34. Gbogbo nǹkan ni a kà tí a sì wọ̀n, gbogbo iye ìwọ̀n ni a sì ṣe àkọsílẹ̀ rẹ̀ sínú ìwé ìgbà náà.

35. Nígbà náà ni àwọn ìgbèkùn tí o ti pada láti ilẹ̀ àjèjì rú ẹbọ ọrẹ sísun sí Ọlọ́run Ísírẹ́lì: akọ màlúù méjìlá fún gbogbo Ísírẹ́lì, àádọ́rùn-ún-o-lé-mẹ́ta akọ ọdọ àgùntàn àti òbúkọ méjìlá fún ọrẹ sísun sí Olúwa.

36. Wọ́n sì jíṣẹ́ àṣẹ ọba fún àwọn ìjòyè àti àwọn baálẹ̀ agbègbè Éúfúrétè, wọ́n sì ṣe ìrànlọ́wọ́ fún àwọn ènìyàn àti ilé Ọlọ́run nígbà náà.

Ẹ́sírà 8