Ẹ́sírà 7:1-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí, ní àkókò ìjọba ọba Aritaṣéṣéṣì ní Páṣíà, Ẹ́sírà ọmọ Ṣéráíyà, ọmọ Ásáríyà, ọmọ Hílíkíyà,

2. Ọmọ Ṣálúmù, ọmọ Ṣádókù, ọmọ Áhítúbì,

3. ọmọ Ámáríyà, ọmọ Ásáríyà, ọmọ Méráíótù,

4. ọmọ Ṣéráháyà, ọmọ Húsì, ọmọ Búkì,

5. ọmọ Ábísúà, ọmọ Fínéhásì, ọmọ Élíásérì, ọmọ Árónì olórí àlùfáà—

6. Ẹ́sírà yìí gòkè wá láti Bábílónì. Olùkọ́ tí ó ní ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa òfìn Mósè, èyí tí Olúwa, Ọlọ́run Ísírẹ́lì, ti fi fún wọn. Ọba sì fi gbogbo ohun tí ó béèrè fún un, nítorí ọwọ́ Olúwa Ọlọ́run wà lára rẹ̀.

Ẹ́sírà 7