Ẹ́sírà 6:21-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

21. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí ó ti dé láti ìgbèkùn jẹ ẹ́ lápapọ̀ pẹ̀lú gbogbo àwọn tí ó ti ya ara wọn kúrò nínú gbogbo iṣẹ́ àìmọ́ ti àwọn kèfèrí aládùúgbò wọn láti wá Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì.

22. Fún ọjọ́ méje, wọ́n ṣe ayẹyẹ Búrẹ́dì tí kò ní Yíìsìtì pẹ̀lú àjẹtì àkàrà. Nítorí tí Olúwa ti kún wọn pẹ̀lú ayọ̀ nípa yíyí ọkàn ọba Ásíríà padà, tí ó fi ràn wọ́n lọ́wọ́ lórí iṣẹ́ ilé Ọlọ́run, Ọlọ́run Ísírẹ́lì.

Ẹ́sírà 6