62. Àwọn wọ̀nyí wá ìwé ìrántí ìdílé wọn, ṣùgbọ́n wọn kò rí i, bẹ́ẹ̀ ni a kò kà wọ́n kún ara àlùfáà nítorí, a kà wọ́n sí aláìmọ́.
64. Gbogbo ìjọ ènìyàn náà jẹ́ (42,360) ẹgbàá mọ́kànlélógún-ó-lé-òjìdínnírinwó.
65. Yàtọ̀ sí ẹgbẹ̀ríndínlẹ́gbàárin-ó-dín mẹ́talélọ́gọ́ta (7,337) ìránṣẹ́ ọkùnrin àti ìránṣẹ́bìnrin; wọ́n ní igba (200) akọrin ọkùnrin àti obìnrin.