Ẹ́sírà 1:1-3 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ní ọdún kìn-ní-ní Ṣáírúsì, ọba Páṣíà, kí a lè mú ọ̀rọ̀ Olúwa tí Jeremáyà sọ ṣẹ, Olúwa ru ọkàn Ṣáírúsì ọba Páṣíà sókè láti ṣe ìkéde jákèjádò gbogbo agbégbé ìjọba rẹ̀, kí ó sì ṣe àkọsílẹ̀ rẹ̀ pé:

2. Èyí ni ohun tí Sáírúsì ọba Páṣíà wí pé: Olúwa, Ọlọ́run ọ̀run, ti fún mi ní gbogbo ìjọba ayé. Ó sì ti yàn mí láti kọ́ tẹ́ḿpìlì Olúwa fún un ní Jérúsálẹ́mù tí ó wà ní Júdà.

3. Ẹnikẹ́ni nínú àwọn ènìyàn rẹ̀ láàárin yín—kí Ọlọ́run rẹ̀ wà pẹ̀lú rẹ̀, kí ó sì gòkè lọ sí Jérúsálẹ́mù tí ó wà ní Júdà, láti kọ́ tẹ́ḿpìlì Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì, Ọlọ́run tí ó wà ní Jérúsálẹ́mù.

Ẹ́sírà 1