11. Wọ́n ti fipá bá àwọn obìnrin wa lò pọ̀ ní Síónì,àti àwọn wúndíá wa ní ìlú Júdà.
12. Àwọn ọmọ ọbakùnrin ti di ṣíṣo sókè ní ọwọ́ wọn;kò sí ìbọ̀wọ̀ fágbà mọ́.
13. Àwọn ọdọ́mọkùnrin wa ru òkúta;àwọn ọmọkùnrin sì ńṣsàárẹ̀ lábẹ́ ẹrù igi.
14. Àwọn àgbààgbà ti lọ kúrò ní ẹnu bodè ìlú;àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin sì dákẹ́ orin wọn
15. Ayọ̀ ti ṣáko ní ọkàn wa;ọ̀fọ̀ sì ti dúró bí ijó fún wa.
16. Adé ti sí kúrò ní orí waÈgbé ni fún wa, nítorí a ti ṣẹ̀.
17. Nítorí èyí, àárẹ̀ mú ọkàn wa,nítorí èyí, ojú wa sì ṣú.
18. Fún òkè Síónì tí ó ti di ahorolórí rẹ̀ àwọn kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ sì ń rìn kiri.
19. Ìwọ, Olúwa, jọba títí láé;ìjọba rẹ dúró láti ìran kan dé ìran mìíràn.
20. Kí ló dé tí o n gbàgbé wa ní gbogbo ìgbà?Kí ló dé tí o fi kọ̀ wá sílẹ̀ fún ọjọ́ pípẹ́?
21. Mú wa padà sí ọ̀dọ̀ rẹ, Olúwa, kí àwa kí ó le padà;mú ọjọ́ wa di tuntun bí ìgbà a nì
22. Àyàfi tí o bá ti kọ̀ wá sílẹ̀ pátápátátí ìbínú rẹ sí wa sì kọjá ìwọ̀n.