Ẹkún Jeremáyà 5:1-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Rántí, Olúwa, ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí wa;wò ó, kí o sì rí ìtìjú wa.

2. Àwọn ohun ìní wa ti di ti àlejò,ilé wa ti di ti àjèjì.

3. Àwa ti di aláìní òbí àti aláìní baba,àwọn ìyá wa ti di opó.

4. A gbọdọ̀ ra omi tí à ń mu;igi wa di títà fún wa.

5. Àwọn tí ó ń lé wa sún mọ́ wa;àárẹ̀ mú wa àwa kò sì rí ìsinmi.

6. Àwa jọ̀wọ́ ara wa fún Éjíbítì àti Ásíríàláti rí oúnjẹ tótó jẹ.

7. Àwọn baba wa ti ṣẹ̀, wọn kò sì sí mọ́,àwa sì ń ru ìjìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn.

Ẹkún Jeremáyà 5