Ékísódù 8:17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)
Wọ́n sì ṣe bẹ́ẹ̀, Nígbà tí Árónì na ọwọ́ rẹ́ jáde pẹ̀lú ọ̀pá ní ọwọ́ rẹ̀, tí ó sì lu eruku ilẹ̀, kòkòrò-kantíkantí sì wà lára àwọn ènìyàn àti àwọn ẹranko wọn. Gbogbo eruku jákè-jádò ilẹ̀ Éjíbítì ni ó di kòkòrò-kantíkantí.