Lẹ́yìn náà ni Mósè àti Árónì tọ Fáráò lọ, wọ́n sì wí pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa, Ọlọ́run Ísírẹ́lì sọ: ‘Jẹ́ kí àwọn ènìyàn mi kí ó lọ, kí wọn kí ó lè ṣe àjọ mi ní ijù.’ ”