19. Wọ́n ṣe òrùka wúrà méjì, wọ́n sì so wọ́n mọ́ igun méjèèjì igbáyà náà ní etí tí ó wà ní inú lẹ́gbẹ̀ẹ́ ẹ̀wù èfòdì náà.
20. Wọ́n sì tún ṣe òrùka wúrà méjì sí i, wọ́n sì so wọ́n mọ́ ìdí aṣọ èjìká ní iwájú ẹ̀wù èfòdì náà tí ó sún mọ́ ibi tí a ṣe lọ́sọ̀ọ́ ní òkè ìgbànú ẹ̀wù èfòdí náà.
21. Wọn ṣo àwọn òrùka igbáàyà mọ́ àwọn òrùka ẹ̀wù èfòdì ọ̀já aṣọ aláró, kí a pa á pọ̀ mọ́ ìgbànú, nítorí kí igbáàyà náà má ṣe tú kúrò lára ẹ̀wù èfòdì náà gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mósè.
22. Ó sì ṣe ọ̀já àmùrè ẹ̀wù èfòdì gbogbo rẹ̀ jẹ́ aṣọ aláró iṣẹ́ alásọ híhun
23. Pẹ̀lú ihò ní àárin ọ̀já àmùrè náà gẹ́gẹ́ bí i ojú kọ́là, àti ìgbànú yí ihò yìí ká, nítorí kí ó má ba à ya.
24. Ó sì ṣe pomégíránátè ti aṣọ aláró, elésèé àlùkò, òdòdó àti ti ọ̀gbọ̀ olókùn dáradára yí ìsẹ́tí ọ̀já àmùrè náà ká.