Ékísódù 34:29-35 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

29. Nígbà tí Mósè sọ̀kalẹ̀ láti orí òkè Ṣínáì pẹ̀lú wàláà ẹ̀rí méjì ní ọwọ́ rẹ̀, òun kò mọ̀ pé ojú òun ń dán nítorí ó bá Olúwa sọ̀rọ̀.

30. Nígbà tí Árónì àti gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì rí Mósè, ojú rẹ̀ ń dán, ẹ̀rù sì ń bà wọ́n láti sún mọ́ ọn.

31. Ṣùgbọ́n Mósè pè wọn; Árónì àti gbogbo àwọn olórí àjọ padà wá bá a, ó sì bá wọn sọ̀rọ̀.

32. Lẹ́yìn èyí gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sún mọ́ ọn, ó sì fún wọn ní gbogbo àṣẹ tí Olúwa fún-un lórí òkè Ṣínáì.

33. Nígbà Mósè parí ọ̀rọ̀ sísọ fún wọn. Ó fi ìbòjú bo ojú rẹ̀.

34. Ṣùgbọ́n nígbàkígbà tí ó bá wà níwájú Olúwa láti bá a sọ̀rọ̀, á sí ìbòjú náà títí yóò fi jáde. Nígbà tí ó bá sì jáde, á sì sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ohun tí a ti pa láṣẹ fún-un,

35. wọ́n sì rí i pé ojú rẹ̀ ń dán. Mósè á sì tún fi ìbòjú bo ojú rẹ̀ títí á fi lọ bá Olúwa sọ̀rọ̀.

Ékísódù 34