Rántí àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ Ábúráhámù, Ísáákì àti Ísírẹ́lì, ẹni tí ìwọ búra fún fúnraàrẹ: ‘tí o wí fún wọn pé, èmi yóò mú irú ọmọ rẹ pọ̀ bí ìràwọ̀ ojú ọ̀run, èmi yóò sì fún irú ọmọ rẹ ní gbogbo ilẹ̀ tí mo ti pinnu fún wọn, yóò sì jẹ́ ogún ìní wọn láéláé.’ ”