16. Nítorí náà ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yóò se máa pa ọjọ ìsinmi mọ́, ẹ máa ṣe àkíyèsí rẹ̀ dé ìrandíràn tó ń bọ̀ bí i májẹ̀mu títí láé.
17. Yóò jẹ́ àmí láàrin èmi àti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì títí láé, nítorí ní ọjọ́ mẹ́fà ni Olúwa dá ọ̀run àti ayé, àti ní ọjọ́ keje ni ó fi iṣẹ́ sílẹ̀, ó sì sinmi.’ ”
18. Nígbà tí Olúwa parí ọ̀rọ̀ ṣíṣọ fún Mósè lórí òkè Ṣínáì, ó fún-un ní òkúta wàláà ẹ̀rí méjì, okuta wàláà òkúta tí a fi ìka Ọlọ́run kọ.