Ékísódù 30:12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)
“Nígbà tí ìwọ bá ka iye àwọn ọmọ Ísírẹ́lì láti mọ iye wọn, ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn gbọdọ̀ mú ìràpadà ọkàn rẹ̀ wá fún Olúwa ní ìgbà tí o bá ka iye wọn. Nígbà náà ni àjàkálẹ̀-àrùn kì yóò sún mọ́ wọn, nígbà tí o bá ń ka iye wọn.