Ékísódù 3:21-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

21. “Èmi yóò sì jẹ́ kí ẹ bá ojúrere àwọn ará Éjíbítì pàdé. Tí yóò fi jẹ́ pé ti ẹ̀yin bá ń lọ, ẹ kò ní lọ ní ọwọ́ òfo.

22. Gbogbo àwọn obìnrin ni ó ní láti béèrè lọ́wọ́ àwọn aládùúgbò wọn àti gbogbo àwọn obìnrin ti ń gbé nínú ilé rẹ fún ohun Sílífà àti wúrà àti fún aṣọ, èyí ti ẹ̀yin yóò wọ̀ sí ọrùn àwọn ọmọ yín ọkùnrin àti obìnrin. Báyìí ni ẹ̀yin yóò sì kó ẹrù àwọn ará Éjíbítì.”

Ékísódù 3