Ékísódù 24:10-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

10. Wọ́n sì rí Ọlọ́run Ísírẹ́lì. Ní abẹ́ ẹṣẹ̀ rẹ̀ ni ohun kan bí i pèpéle ti a fi òkúta sáfírè ṣe wà. Èyí ti ó mọ́ niṣínniṣín bí àwọ̀ sánmọ̀ fúnraarẹ̀.

11. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run kò gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè sí àwọn àgbààgbà Ísírẹ́lì wọ̀nyí; wọ́n ri Ọlọ́run, wọ́n jẹ, wọ́n sì mu.

12. Olúwa sì sọ fún Mósè pé, “Gòkè wá sí ọ̀dọ̀ mi, kí o sì dúró níhín-ín. Èmi yóò sì fún ọ ní òkúta ìkọ̀wé pẹ̀lú òfin àti ìlànà tí mo ti kọ sílẹ̀ fún ìtọ́sọ́nà wọn.”

13. Nígbà náà ni Mósè jáde lọ pẹ̀lú Jọsúà arákùnrin rẹ̀. Mósè lọ sí orí òkè Ọlọ́run.

14. Ó sì wí fún àwọn àgbààgbà pé, Ẹ dúró dè wá níhìn-ín yìí, títí àwa yóò fi tún padà tọ̀ yín wá, sì kíyèsìí, Árónì àti Húrì ń bẹ pẹ̀lú yín, bí ẹnikan bá ni ọ̀ràn kan, kí ó tọ̀ wọ́n lọ.

15. Nígbà tí Mósè gun orí òkè lọ, ìkúúkùù bo orí òkè náà.

Ékísódù 24