1. Ní ìgbà náà ni Olúwa sọ fún Mósè pé, “Gòkè tọ Olúwa wá, ìwọ àti Árónì, Nádábú àti Ábíhù àti àádọ́rin (70) àwọn àgbààgbà Ísírẹ́lì. Ẹ̀yin kì ó sìn ni òkèèrè réré.
2. Ṣùgbọ́n Mósè nìkan ṣoṣo ni yóò súnmọ́ Olúwa; àwọn tókù kò gbọdọ̀ súnmọ́ tòsí ibẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ènìyàn kò gbọdọ̀ gòkè wá pẹ̀lú rẹ̀.”
3. Nígbà ti Mósè lọ láti sọ fún àwọn ènìyàn, gbogbo ọ̀rọ̀ àti òfin Olúwa, wọ́n wí ní ohùn kan pé, “Gbogbo ohun ti Olúwa wí ni àwa yóò ṣe.”
4. Nígbà náà ni Mósè kọ gbogbo ohun tí Olúwa sọ sílẹ̀.Ó dìde ní kùtùkùtù òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, ó sì mọ pẹpẹ ni ẹsẹ̀ òkè náà. Ó se ọ̀wọ́n òkúta méjìlá. Èyí ti ó dúró fún àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì méjìlá.
5. Nígbà náà ni ó rán àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin Ísírẹ́lì, wọ́n sì rúbọ sísun, wọ́n fi ọ̀dọ́ màlúù rú ẹbọ àlàáfíà si Olúwa.
6. Mósè bu ìlàjì ẹ̀jẹ̀ ẹran sínú abọ́, ó sì fi ìlàjì tókù wọn ara pẹpẹ.
7. Nígbà náà ni ó sì mú ìwé májẹ̀mú, ó sì kà á sí àwọn ènìyàn. Wọ́n dáhùn pé, “Àwa yóò ṣe gbogbo ohun tí Olúwa wí: Àwa yóò sì gbọ́ràn.”
8. Nígbà náà ni Mósè gbé ẹ̀jẹ̀, ó sì wọn sí àwọn ènìyàn náà lára pé, “Èyí ni ẹ̀jẹ̀ májẹ̀mú tí Ọlọ́run ti ṣe pẹ̀lú yín ni ìbámu pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí.”
9. Mósè àti Árónì, Nádábù àti Ábíhù àti àádọ́rin àwọn àgbààgbà Ísírẹ́lì gòkè lọ.
10. Wọ́n sì rí Ọlọ́run Ísírẹ́lì. Ní abẹ́ ẹṣẹ̀ rẹ̀ ni ohun kan bí i pèpéle ti a fi òkúta sáfírè ṣe wà. Èyí ti ó mọ́ niṣínniṣín bí àwọ̀ sánmọ̀ fúnraarẹ̀.