14. Nígbà tí ìrì tí ó sẹ̀ bo ilẹ̀ ti lọ, kíyèsí i, ohun tí ó dì, tí ó sì ń yooru bí i yìnyín wà lórí ilẹ̀.
15. Nígbà tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì rí i, wọ́n bi ara wọn léèrè pé, “Kí ni èyí?” Nítorí pé wọn kò mọ ohun tí i se.Mósè sì wí fún wọn pé, “Èyí ni oúnjẹ tí Olúwa fi fún un yín láti jẹ.
16. Èyí ni ohun tí Olúwa ti pàṣẹ: ‘Kí olúklùkù máa kó èyí ti ó tó fún un láti jẹ. Ẹ mú òṣùnwọ̀n ómérì kan (bí i líta méjì) fún ẹnikọ̀ọ̀kan ti ó wà nínú àgọ́ yín.’ ”
17. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì ṣe bí a ti sọ fún wọn; àwọn kan kó púpọ̀, àwọn kan kó kékeré.
18. Nígbà ti wọn fi òṣùwọ̀n ómérì wọ̀n-ọ́n-nì, ẹni ti ó kó púpọ̀ kò ní púpọ̀ jù, bẹ́ẹ̀ ni ẹni tí ó kó ìwọ̀nba kò ní kéré jù. Ẹnìkọ̀ọ̀kan kó ìwọ̀nba ti ó tó fún un.
19. Mósè sì wí fún wọ́n pé, “Kí ẹnikẹ́ni ó má ṣe kó pamọ́ lára rẹ̀ di òwurọ̀ ọjọ́ kejì.”
20. Ṣùgbọ́n, àwọn kan nínú wọn kò fetí sí Mósè; Wọ́n kó lára rẹ̀ pamọ́ di òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, ohun ti wọ́n kó pamọ́ kún fún ìdin, ó sì ti bẹ̀rẹ̀ sí ní rùn. Nítorí náà Mósè bínú sí wọn.
21. Ní òwúrọ̀, ni ojoojúmọ́ ni ẹnìkọ̀ọ̀kan ń lọ kó ìwọ̀nba ti ó tó fún un láti jẹ, bí òòrùn bá sì mú, a sì yọ́.
22. Ní ọjọ́ kẹfà, wọ́n kó ìlọ́po méjì èyí ti wọn ń kó tẹ́lẹ̀: òṣùnwọn ómérì méjì fún ẹnìkọ̀ọ̀kan; àwọn olórí ìjọ ènìyàn sì wá, wọ́n sì sọ èyí fún Mósè.
23. Ó sì wí fún wọn pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa pàṣẹ: ‘Ọ̀la jẹ́ ọjọ́ ìsinmi, ìsinmi mímọ́ fún Olúwa. Ẹ yan èyí ti ẹ̀yin ní yan, kí ẹ sì bọ èyí ti ẹ̀yin ní bọ̀. Ẹ tọ́jú èyí ti ó kù sílẹ̀, kí ẹ pa á mọ́ di òwúrọ̀.’ ”
24. Wọ́n sì tọ́jú rẹ̀ di òwúrọ̀ bí Mósè ti pàṣẹ; kò sì rùn bẹ́ẹ̀ ni kò sì ní ìdin.
25. Mósè sì wí fún wọn pé, “Ẹ jẹ ẹ́ ní òní nítorí òní jẹ́ ọjọ́ ìsinmi Olúwa. Ẹ̀yin kò ni rí i ni orí ilẹ̀ ní ọjọ́ òní.
26. Ní ọjọ́ mẹ́fà ni kí ẹ fi kó o, ṣùgbọ́n ni ọjọ́ keje ọjọ́ ìsinmi, kò ní sí i fún un yín ni ọjọ́ náà.”