Éfésù 4:16-32 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

16. Láti ọ̀dọ̀ ẹni ti ara náà tí a ń so ṣọ̀kan pọ̀, tí ó sì ń fi ara mọ́ra, nípaṣẹ̀ oríkèé kọ̀ọ̀kan tí a ti pèsè, nígbà tí ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan bá ń ṣiṣẹ́ dáradára, yóò mú ara dàgbà, yóò sì gbé ara òun tìkárárẹ̀ dìde nínú ìfẹ́.

17. Ǹjẹ́ èyí ni mo ń wí, tí mo sì ń jẹ́rìí nínú Olúwa pé, láti ìsinsin yìí lọ, kí ẹ̀yin má ṣe rìn mọ́, àní gẹ́gẹ́ bí àwọn aláìkọlà ti ń rìn nínú ìrònú asán wọn.

18. Òye àwọn ẹni tí ó ṣókùnkùn, àwọn tí ó sì di àjèjì sí ìwà-bí-Ọlọ́run nítorí àìmọ̀ tí ń bẹ nínú wọn, nítorí lílè ọkàn wọn.

19. Àwọn ẹni tí ọkàn wọn le rékọjá, tí wọ́n sì ti fi ara wọn fún wọ̀bìà, láti máa fi ìwọ́ra ṣiṣẹ́ ìwà èérí gbogbo.

20. Ṣùgbọ́n a kò fi Kírísítì kọ́ yín bẹ́ẹ̀.

21. Bí ó bá ṣe pé nítòótọ́ ni ẹ ti gbóhùn rẹ̀ ti a sì ti kọ́ yín nínú rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí otítọ́ ti ń bẹ nínú Jésù.

22. Pé, ní tì ìwà yín àtijọ́, kí ẹ̀yin bọ́ ogbologbo ọkùnrin nì sílẹ̀, èyí tí ó díbàjẹ́ gẹ́gẹ̀ bí ìfẹ́kúfẹ́ ẹ̀tàn;

23. Kí ẹ sì di titun ni ẹ̀mí inú yín;

24. Kí ẹ sì gbé ọkùnrin titun wọ̀, èyí tí a dá ni àwòrán Ọlọ́run nínú òdodo àti ìwà mímọ́ ti òtítọ́.

25. Nítorí náà ẹ fi èké ṣiṣe sílẹ̀, ki olúkúlùkù yín máa ba ọmọnìkejì rẹ̀ sọ òtítọ́, nítorí ẹ̀yà ara ọmọnìkejì wa ni àwá jẹ́.

26. Nínú ìbínú yín, ẹ máa ṣe ṣẹ̀, ẹ má ṣe jẹ́ kí òòrùn wọ̀ bá ìbínú yín:

27. Bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ má ṣe fi àyè fún Èṣù.

28. Kí ẹni tí ń jalè má ṣe jalè mọ́: ṣùgbọ́n kí ó kúkú máa ṣe làálàá, kí ó máa fi ọwọ́ rẹ̀ ṣiṣẹ́ ohun tí ó dara, kí òun lè ní láti pín fún ẹni tí ó ṣe aláìní.

29. Ẹ má ṣe jẹ́ kí ọ̀rọ̀ ìdibàjẹ́ kan ti ẹnu yín jáde, ṣùgbọ́n irú èyí ti o dara fún ẹ̀kọ́, kí ó lè máa fi oore ọ̀fẹ́ fún àwọn tí ń gbọ́.

30. Ẹ má sì ṣe mú Ẹ̀mí Mímọ́ Ọlọ́run bínú, ẹni tí a fi ṣe èdìdì yín dé ọjọ́ ìdáǹdè.

31. Gbogbo ìwà kíkorò àti ìbínú, àti ìrunú, àti ariwo, àti ọ̀rọ̀ búburú ni kí a mú kúrò lọ́dọ̀ yín, pẹ̀lú gbogbo àránkan:

32. Ẹ máa ṣoore fún ọmọnìkéjì yín, ẹ ní ìyọ́nú, ẹ máa dáríji ara yín, gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run nínú Kírísítì ti dáríjì yín.

Éfésù 4