Éfésù 4:1-3 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Nítorí náà, èmi òǹdè nínú Olúwa ń bẹ̀ yín pé kí ẹ̀yin máa gbé ìgbé ayé tí ó yẹ sí ìpè tí a pè yín sí.

2. Pẹ̀lu ìrẹ̀lẹ̀ gbogbo àti inú tútù, pẹ̀lú ìpamọ́ra, ẹ máa fi ìfẹ́ faradà fún ẹnìkejì yín.

3. Kí ẹ sì máa làkàkà láti pa ìṣọ̀kan Ẹ̀mí mọ́ ni ìdàpọ̀ àlàáfíà.

Éfésù 4