25. Dá iná sun àwọn ère òrìṣà wọn, ẹ má ṣe ṣe ojúkòkòrò sí fàdákà tàbí wúrà tí ó wà lára wọn. Ẹ má ṣe mú un fún ara yín, bí bẹ́ẹ̀ kọ́ yóò jẹ́ ìdẹkùn fún un yín, torí pé ìríra ni sí Olúwa Ọlọ́run yín.
26. Ẹ má ṣe mú ohun ìríra wá sí ilé yín, kí ìwọ má bàá di ẹni ìparun bí i rẹ̀. Ẹ kóríra rẹ̀ kí ẹ sì kàá sí ìríra pátapáta, torí pé a yà á sọ́tọ̀ fún ìparun ni.