20. Pẹ̀lúpẹ̀lù, Olúwa Ọlọ́run yín yóò rán oyin sáàrin wọn títí tí àwọn tí ó sálà tí wọ́n sápamọ́ fún un yín, yóò fí ṣègbé.
21. Ẹ má gbọ̀n jìnnìjìnnì torí wọn, torí pé Olúwa Ọlọ́run yín tí ó wà láàrin yín, Ọlọ́run alágbára ni, àti Ọlọ́run tí ó tóbi lọ́pọ̀lọpọ̀.
22. Olúwa Ọlọ́run yín yóò lé gbogbo orílẹ̀ èdè wọ̀n-ọn-nì kúrò níwájú u yín díẹ̀díẹ̀. A kò ní gbà yín láàyè láti lé wọn dànù lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo. Kí àwọn ẹranko ìgbẹ́ má baà gbilẹ̀ sí i láàrin yín.
23. Ṣùgbọ́n Olúwa Ọlọ́run yín yóò fi wọ́n lée yín lọ́wọ́, yóò sì máa fà wọ́n sínú un dàrúdàpọ̀ títí tí wọn yóò fi run.