Deutarónómì 6:13-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

13. Bẹ̀rù Olúwa Ọlọ́run rẹ, Òun nìkan ni kí o sì máa sìn, búra ní orúkọ rẹ̀ nìkan.

14. Ẹ má ṣe tẹ̀lé ọlọ́run mìíràn: ọlọ́run àwọn tí ó yí i yín ká;

15. torí pé Olúwa Ọlọ́run yín tí ó wà láàrin yín, Ọlọ́run owú ni, ìbínú rẹ̀ yóò sì run yín kúrò ní ilẹ̀ náà.

16. Ẹ má ṣe dán Olúwa Ọlọ́run yín wò bí ẹ ti ṣe ní Máṣà.

17. Ẹ rí i dájú pé ẹ̀ ń pa àwọn òfin Olúwa Ọlọ́run yín mọ́ àti àwọn àṣẹ àti àwọn ìlànà tí ó ti fún un yín.

Deutarónómì 6