5. Nígbà ogójì ọdún tí mò ń tọ́ yín sọ́nà ní ihà, aṣọ ọ̀ rẹ kò gbó tàbí bàtà ẹṣẹ̀ rẹ.
6. O kò jẹ oúnjẹ tàbí mu wáìnì kankan tàbí rú ohun mímu mìíràn. Mo ṣe èyí kí o lè mọ̀ pé èmi ni Olúwa Ọlọ́run rẹ.
7. Nígbà tí o dé ibí yìí, Ṣíhónì ọba Hésíbónì àti Ógù ọba Básánì jáde wá láti bá ọ jà, ṣùgbọ́n a sẹ́gun wọn.
8. A gba ilẹ̀ wọn a sì fi fún àwọn ọmọ Rúbẹ́nì, àti àwọn ọmọ Gádì, àti ààbọ̀ ẹ̀yà Mánásè bí ogún.
9. Rọra máa tẹ̀lé ìpinnu májẹ̀mú yìí, kí o lè ṣe rere nínú gbogbo ohun tí o bá ń ṣe.
10. Gbogbo yín ń dúró lónìí yìí níwájú Olúwa Ọlọ́run rẹ: adarí ì rẹ àti olórí àwọn ọkùnrin, àwọn àgbààgbà rẹ àti àwọn olóyè àti gbogbo àwọn ọkùnrin mìíràn ní Ísírẹ́lì,
11. pẹ̀lú gbogbo àwọn ọmọ ọ̀ rẹ àti ìyàwó ò rẹ àti àwọn àlejò tí wọ́n ń gbé ní àgọ́ ọ̀ rẹ, tí ó ké pópòpó igi rẹ, tí ó sì gbé omi ì rẹ.
12. O dúró níhìn ín yìí kí o lè wọ inú májẹ̀mú pẹ̀lú Olúwa Ọlọ́run rẹ, májẹ̀mú tí Olúwa ń ṣe pẹ̀lú ù rẹ lónìí yìí àti tí óun dè pẹ̀lú ìbúra,
13. láti jẹ́wọ́ rẹ lónìí yìí bí ènìyàn an rẹ̀, pé kí ó lè jẹ́ Ọlọ́run rẹ bí ó ti ṣèlérí àti bí ó ti ṣe ìbúra fún àwọn baba à rẹ Ábúráhámù, Ísákì àti Jákọ́bù.
14. Èmi ń ṣe májẹ̀mú yìí, pẹ̀lú ìbúra rẹ̀, kì í ṣe fún ìwọ nìkan
15. tí ó dúró níbí pẹ̀lú wa lónìí níwájú Olúwa Ọlọ́run wa ṣùgbọ́n àti fún gbogbo àwọn tí kò sí níbí lónìí.