Deutarónómì 28:66-68 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

66. Ìwọ yóò gbé ní ìdádúró ṣinṣin, kún fún ìbẹ̀rù-bojo lọ́sàn án àti lóru, bẹ́ẹ̀ kọ́ láé ni ìwọ yóò rí i ní àrídájú wíwà láyé rẹ.

67. Ìwọ yóò wí ní òwúrọ̀ pé, “Bí ó tilẹ̀ lè jẹ́ pé ìrọ̀lẹ́ níkan ni!” nítorí ẹ̀rù tí yóò gba ọkàn rẹ àti ìran tí ojú rẹ yóò máa rí.

68. Olúwa yóò rán ọ padà nínú ọkọ̀ sí Éjíbítì sí ìrìnàjò tí mo ní ìwọ kì yóò lọ mọ́. Níbẹ̀ ni ìwọ yóò tún fi ara rẹ fún àwọn ọ̀ta à rẹ gẹ́gẹ́ bí ẹrúkùnrin àti ẹrúbìnrin, ṣùgbọ́n kò sí ẹni tí yóò rà ọ́.

Deutarónómì 28