Deutarónómì 25:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Nígbà tí àwọn ènìyàn méjì bá ń jà, kí wọn kó ẹjọ́ lọ sí ilé ìdájọ́, kí àwọn onídàájọ́ dá ẹjọ́ náà, kí wọn dá àre fún aláre àti ẹ̀bi fún ẹlẹ́bi.

2. Bí ó bá tọ́ láti na ẹlẹ́bi, kí onídàájọ́ dá a dọ̀bálẹ̀ kí a sì nà án ní ojú u rẹ̀ ní iye pàsán tí ó tọ́ sí ẹ̀ṣẹ̀ tí ó sẹ̀.

3. Ṣùgbọ́n kò gbọdọ̀ fún un ju ogójì pàsán lọ. Bí ó bá nà án ju bẹ́ẹ̀ lọ, arákùnrin rẹ̀ yóò di ẹni ìrẹ̀sílẹ̀ ní ojú rẹ̀.

4. Má ṣe di akọ màlúù lẹ́nu nígbà tí o bá ń pa ọkà.

Deutarónómì 25