Deutarónómì 23:10-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

10. Bí ọ̀kan nínú àwọn ọkùnrin rẹ bá jẹ́ aláìmọ́ nítorí ìtújáde tí ó ní, o ní láti jáde kúrò nínú àgọ́, kí o má ṣe wọ inú àgọ́.

11. Ṣùgbọ́n nígbà tí ó bá di ìrọ̀lẹ́ o ní láti wẹ ara rẹ, àti ní àṣálẹ́ kí o padà sínú àgọ́.

12. Sàmì sí ibìkan lóde àgọ́, níbi tí o lè máa lọ láti dẹ ara rẹ lára.

13. Ìwọ yóò mú igi pẹ̀lú ohun ìjà rẹ àti nígbà tí o bá dẹ ara rẹ lára tán, gbẹ́ kòtò kí o sì bo ìgbẹ́ rẹ.

Deutarónómì 23