Deutarónómì 14:11-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

11. Ẹ lè jẹ ẹyẹ tí ó bá mọ́.

12. Ṣùgbọ́n ìwọ̀nyí ní ẹ kò gbọdọ̀ jẹ: idì, igún, àkàlà,

13. onírúurú àṣá àti àṣá alátagbà,

14. onírúurú ẹyẹ ìwò,

15. ògòǹgò, òyo, pẹ́pẹ́yẹdò àti onírúurú àwòdì,

16. onírúurú òwìwí,

17. òwìwí-ọ̀dàn, idì-okùn, ẹyẹ-àkọ̀,

18. òòdẹ̀, onírúurú ẹyẹ odò mìíràn, atọ́ka àti àdán.

19. Àti gbogbo kòkòrò tí ń fò tí wọ́n ń kọ́wọ̀ọ́ rín jẹ́ aláìmọ́ fun un yín, ẹ má ṣe jẹ wọ́n.

20. Ṣùgbọ́n ẹ lè jẹ èyíkéyí ẹ̀dá abìyẹ́ tí ó bá mọ́.

21. Ẹ má ṣe jẹ ohun tí ó ti kú sílẹ̀. Ẹ lè fún àwọn àjèjì tí ń gbé ní èyíkéyí nínú ìlú yín. Òun lè jẹ ẹ́ tàbí kí ẹ tà á fún àwọn àjèjì. Ṣùgbọ́n ènìyàn mímọ́ fún Olúwa Ọlọ́run yín ni ẹ̀yin jẹ́.Má ṣe ṣe ewúrẹ́ nínú wàrà ìyá rẹ̀.

Deutarónómì 14