23. Èrò náà sì dára lójú mi, torí èyí ni mo ṣe yan àwọn ènìyàn méjìlá nínú yín, ẹnìkan láti inú ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan.
24. Wọ́n sì gòkè lọ sí ilẹ̀ òkè náà, wọ́n sì wá sí pẹ̀tẹ́lẹ̀ Ésíkónì, wọ́n sì yẹ̀ ẹ́ wò.
25. Wọ́n sì mú lára èso ilẹ̀ náà wá fún wa pé, “Ilẹ̀ tí ó dára ni Olúwa Ọlọ́run wa fún wa.”
26. Ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò fẹ́ gòkè lọ; ẹ ṣọ̀tẹ̀ sí àṣẹ Olúwa Ọlọ́run yín.
27. Ẹ kùn nínú àgọ́ ọ yín, ẹ sì wí pé, “Olúwa kórìíra wa, torí èyí ló fi mú wa jáde láti Éjíbítì láti fi wá lé àwọn ará Ámórì lọ́wọ́ láti pa wá run.
28. Níbo la ó lọ? Àwọn arákùnrin wa ti kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá wa nípa sísọ pé, ‘Àwọn ènìyàn náà lágbára wọ́n sì ga jù wá lọ; àwọn ìlú náà tóbi jọjọ bẹ́ẹ̀ ni odi wọn ga kan ọ̀run. A tilẹ̀ rí àwọn òmìrán (Ará Ánákì) níbẹ̀.’ ”
29. Nígbà náà ni mo sọ fún un yín pé, “Ẹ má ṣojo, ẹ kò sì gbọdọ̀ bẹ̀rù wọn.
30. Olúwa Ọlọ́run yín, tí ń ṣáájú yín yóò jà fún un yín; bí ó ti ṣe fún un yín ní Éjíbítì lójú ẹ̀yin tìkárayín
31. àti ní ihà. Níbẹ̀ ni ẹ ti rí i bí Olúwa Ọlọ́run yín ti gbé yín, bí baba ti í gbé ọmọ rẹ̀, ní gbogbo ọ̀nà tí ẹ lọ títí ẹ fi padà dé ibí yìí.”
32. Pẹ̀lú gbogbo èyí tí mo wí, ẹ kò gbẹ́kẹ̀lé Olúwa Ọlọ́run yín,
33. tí ń ṣáájú u yín lọ ní gbogbo ọ̀nà an yín, nípa fífi iná ṣe amọ̀nà an yín ní òru àti ìkùukù ní ọ̀sán, láti fi àwọn ibi tí ẹ lè tẹ̀dó sí hàn yín àti àwọn ọ̀nà tí ẹ ó rìn.