Dáníẹ́lì 9:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ní ọdun kìn-ín-ní Dáríúsì ọmọ Áhásúérésì, ẹni tí a bí ní Médíà, òun ló jẹ ọba lórí ìjọba Bábílónì.

2. Ní ọdun kìn-ín-ní ijọba rẹ̀, èmi Dáníẹ́lì fi iyè sí i láti inú ìwé, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Olúwa tí wòlíì Jeremáyà, wá pé, àádọ́rin ọdún ni Jérúsálẹ́mù yóò fi wà ní ahoro.

3. Nígbà náà, ni mo yípadà sí Olúwa Ọlọ́run, mo bẹ̀ẹ́ pẹ̀lú àdúrà àti ẹ̀bẹ̀, pẹ̀lú ààwẹ̀, aṣọ ọ̀fọ̀ àti eérú.

4. Mo gbàdúrà sí Olúwa Ọlọ́run mi, mo sì jẹ́wọ́ wí pé:“Iwọ Olúwa, Ọlọ́run tí ó tóbi, tí ó sì ní ẹ̀rù, ẹni tí ń pa májẹ̀mú ìfẹ́ mọ́, pẹ̀lú àwọn tí ó ní ìfẹ́ rẹ̀ àti àwọn tí ó ń pa àwọn òfin rẹ̀ mọ́.

Dáníẹ́lì 9